Elizabeth Stamatina "Tina"Fey (/feɪ/; tí a bí ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù karùn-ún ọdún 1970) jẹ́ òṣerébìnrin, aláwàdà ọmọ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà. Fey wà lára àwọn tí ó ko eréNBCsketch comedy tí àkọlé rẹ̀ jẹ́Saturday Night Live láti ọdún 1997 títí di 2006. Òun ni ó sagbátẹ̀rùsitcom30 Rock (2006–2013, 2020) àti eréNetflix tí àkọlé rẹ̀ jẹ́Unbreakable Kimmy Schmidt (2015–2020). Fey tún gbajúmò fún ipa rẹ̀ nínú àwọn eré biMean Girls (2004),Baby Mama (2008),Date Night (2010),Megamind (2010),Muppets Most Wanted (2014),Sisters (2015),Whiskey Tango Foxtrot (2016),Wine Country (2019),Soul (2020), àtiA Haunting in Venice (2023).
Fey tí gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì-ẹyẹ biàmì ẹyẹ Primetime Emmy mẹ́sàn-án,Golden Globe Awards mẹ́ta,àmì ẹyẹ Screen Actors Guild márùn-ún, àtiàmì ẹyẹ Writers Guild of America méje. Ní ọdún 2008,Associated Press fún Fey ní àmì ẹyẹ AP Entertainer fún ọdún náà fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Sarah Palin níSNL. Ní ọdún 2010, Fey tún gbà àmì ẹyẹMark Twain Prize for American Humor.
A bí Elizabeth Stamatina Fey ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù Kàrún ọdún 1970[1][2] níUpper Darby Township, Delaware County,Pennsylvania. Bàbá rẹ̀, Donald Henry Fey, wà lára àwọn tí ó fìgbà kan ja ogun ní orílẹ̀ èdèKorea, ó fìgbà kan jẹ́ adaríYunifásítì ti Pennsylvania àtiYunifásítì Thomas Jefferson.
- ↑"Monitor". Entertainment Weekly (Time Inc.) (1207): p. 29. May 18, 2012.
- ↑Mock, Janet."Tina Fey Biography".People. p. 1. Archived fromthe original on March 29, 2011. RetrievedJune 24, 2009. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help)