Awon nómbà Àdàkọ:Nọ́mbà Nọ́mbà jẹ́ ohun afòyemò tó dúró fún iye tàbíìwòn .Àmì-ìsojú fún nọ́mbà ní àn pé nìàmìnọ́mbà (numeral). Nì èdè ojojúmọ́, à n lo àwọn àmìnọ́mbà bí àkólé (fún àpẹrẹ nọ́mbà tẹlífònù, nọ́mbà ilé). Nínú ìmọ̀ ìṣirò ìtumò nọ́mbà tí s'àkomọ̀ àwọn nọ́mbà afóyemọ̀ bíidà (fraction), nọ́mbà apáòsì (negative), tíkòníònkà (transcendental) àti nọ́mbà tósòro (complex).
Àwọn ònàìṣèṣirò nọ́mbà bíàropò ,ìyokúrò ,ìsodípúpò , àtiìṣepínpín ní a n sewadi wón nínú ẹ̀kaìmọ̀ ìṣirò tí a mò síaljebra afòyemọ̀ (abstract algebra), níbití a tí n sewadi àwọn ònà nọ́mbà afóyemọ̀ bíẹgbẹ́ (group),òrùka (ring) àtipápá (field).
Awa nilo ranti pé a ni orisirisi ona lati awon iye, apeere je 230, ni ede Yoruba e le so "ojì-din-lẹwá-lé-nígba" tabi " Ọgbọnwolerugba"[ 1]
0 - Òdo
1 - Ọkàn
2 - Méjì
3 - Mẹ́ta
4 - Mẹ́rin
5 - Márùn
6 - Mẹ́fà
7 - Méje
8 - Mẹ́jọ
9 - Mẹ́sàn
10 - Mẹ́wàá
11 - Mọ́kànlá
12 - Méjìlá
13 - Mẹ́tàlá
14 - Mẹ́rìnlá
15 - mẹ́ẹ̀ẹ́dógún / Marundinlogun
16 - Mẹ́rìndínlógún
17 - Mẹ́tà-dínlógún
18 - Méjì-dínlógún
19 - Mọ́kàn-dínlógún
20 - Ogún
21 - Ọkànlélógún
22 - Méjìlélógún
23 - Mẹ́tàlélógún
24 - Mẹ́rìnlélógún
25 - Marundinlogbon / Mẹẹdọ́gbọ̀n
26 - Mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n
27 - Mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n
28 - Méjì-dínlọ́gbọ̀n
29 - Mọ́kàn-dínlọ́gbọ̀n
30 - Ọgbọ́n
40 - Ogójì
50 - Àádọ́ta
60 - Ọgọ́ta
70 - Àádọ́rin
80 - Ọgọrin
90 - Àádọ́rùn
100 - Ọgọ́rùn[ 2] [ 3]
110 - Àádọfà
120 - Ọgọfà
130 - Àádóje
140 - Ọgóje
150 - Àádójo
160 - Ọgọjọ
170 - àádọ́sàn / àádọ́sàn án / Igba kan ó-dinógbòn
180 - Ọgọsàn- / Ọgọsàn-án
190 - àádọ́wá
200 - Igba
300 - ọ̀ọ́dúnrún
400 - Irínwó
500 - ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta
600 - ẹgbẹ̀ta
700 - ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin
800 - ẹgbẹ̀rin
900 - ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún
1,000 - ẹgbẹ̀rún
2,000 - ẹgbàá[ 4]
3,000 - ẹgbẹ̀ẹ́dógún
4,000 - ẹgbàajì
5,000 - ẹgbẹ̀rún márùn-ún / ẹgbẹ̀rún márùn
6,000 - ẹgbẹ̀ta
7,000 - ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin[ 5]
8,000 - ẹgbàá-mẹ́rin
9,000 - ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárún
10,000 - ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá / ẹgbàarùn-ún
20,000 - ọ̀kẹ́ / ẹgbàáwá[ 6]
100,000 - ọ̀kẹ́ márùn-ún / ẹgbẹ̀rún ọgọ́rùn-ún
200,000 - ọ̀kẹ́ mẹ́wàá
1,000,000 - ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún / àádọ́ta ọ̀kẹ́ / egbélégbè
10,000,000 - ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá / egbélégbè mẹ́wàá
100,000,000 - ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún ọgọ́rùn / egbélégbè ọgọ́rùn
1,000,000,000 - egbélégbèji
10,000,000,000 - egbélégbèta
100,000,000,000 - egbélégbèrin
1,000,000,000,000 - egbélégbàrun
10,000,000,000,000 - egbélégbèfa
100,000,000,000,000 - egbélégbèje
1,000,000,000,000,000 - egbélégbèjo
10,000,000,000,000,000 - egbélégbèsan
100,000,000,000,000,000 - egbélégbèwa
1,000,000,000,000,000,000 - egbélégbokonla
10,000,000,000,000,000,000 - egbélégbèjila
100,000,000,000,000,000,000 - egbélégbètala
1,000,000,000,000,000,000,000 - egbélégbarundinlogun
∞ tabi (infinity) - àìníye