Mahershala Ali (/məˈhɜrʃələ/; tí orúkọ àbísọ rẹ̀ ń jẹ́Mahershalalhashbaz Gilmore, tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kejì, ọdún 1974) jẹ́ òṣèrékùnrin látiorílẹ̀-èdè Amerika. Ó ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì-ẹ̀yẹ bíiAcademy Awards méjì, Golden Globe Award àti Primetime Emmy Award. Ìwé ìròyìnTimes to orúkọ rẹ̀ pọ̀ mó àwọn ọgọ́rùn-ún ènìyàn tó lọ́á jù lọ ní àgbááyé, ní ọdún 2019,[2] àti 2020,The New York Times fi sípò karùn-úndínlọ́gbọ̀n lára àọn òṣèré tó lọ́lá jù lọ.[3]
Wọ́n bí Ali ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kejì, ọdún 1974, síOakland, California.[4][5] Ó jẹ́ ọmọ Willicia Goines (tí wọ́n bí ní ọdún 1957) àti Phillip Gilmore (tí wọ́n bí ní ọdún 1956 tó sì di olóògbé ní ọdún 1994).[6] Wọ́n tọ́ ọ lọ́nà onígbàgbọ́ ní Hayward, California. Ìyá rẹ̀ tó jẹ́ òjíṣẹ́ Olúwa ní ìjọ Baptist ló tọ́ ọ dàgbà.[7][8][6] Bàbá rè jẹ́ eléré orí-ìtàgé tó ti farahàn nínú eré Broadway.[8][6] Maher-shalal-hash-baz jẹ́ orúkọ ọmọ kejì tí wòlíì Isaiah bí (a lè rí èyí nínú Bíbélì, nínú ìwé Isaiah, orí kẹjọ).[6]
Ilé-ìwé St. Mary's College of California (SMC) ní Moraga, California ni ó lọ, ó sì kẹ́kọ̀ọ́ gboyè lọ́dún 1996 pẹ̀lú ìwé-èrí nínú mass communication.[7] Ó wọ ilé-ìwé náà pẹ̀lú ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ ti àwọn oní basketball, ó sì ń gba bọ́ọ̀lù náà lábẹ́ orúkọ "Hershal Gilmore" .[9]
Gbogbo ènìyàn mọ Ali pẹ̀lú àpètán orúkọ rẹ̀ Mahershalalhashbaz Ali, ó lo èyí láti ọdún 2001 títí wọ ọdún 2010, nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ní lo Mahershala Ali.[7][10]
Àwọn ènìyàn tún mọ̀ ọ́ látàrí èdá-ìtàn tó ṣe gégé bíi Remy Danton nínú eréNetflix tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́House of Cards, ó tún ṣe Cornell Stokes nínúMarvel's Luke Cage, ó ṣe Colonel Boggs nínúThe Hunger Games: Mockingjay – Part 1 àtiThe Hunger Games: Mockingjay – Part 2 àti Tizzy nínú fíìmù 2008The Curious Case of Benjamin Button, tó jẹ́ eré àkọ́kọ́ rẹ̀. Àwọn eré mìí ràn tó ti ṣe niPredators,The Place Beyond the Pines,Free State of Jones,Hidden Figures.
Ó ti gba àwọn àmì-èyẹ Academy Award for Best Supporting Actor, SAG Award àti Critics' Choice Award àti BAFTA Award. Níbi 89th Academy Awards, òun ni mùsùlùmí àkọ́kọ́ tó gba àmì-ẹ̀ye Oscar.[11]
Ali darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ olórin Bay Area recording label ní ọdún 2000.Orúkọ rẹ̀ sì niPrince Ali.[12] Ní ọdún 2006, ó gbé orin àkọ́kọ́ rẹ̀ jáde, tí ń ṣeCorner Ensemble, lẹ́yìn náà, ó gbé orin mìíràn jáde bíiCurb Side Service ní ọdún 2007.[13]