Moulay Ismail Ibn Sharif (Lárúbáwá:مولاي إسماعيل بن الشريف), tí a bí ní 1645 níSijilmassa tí ó sì fi ayé sílẹ̀ ní ọjọ́ kejìlélógún oṣù kẹta oṣù 1727 níMeknes, jẹ́Sultan Morocco láti ọdún 1672 sí 1727, gẹ́gẹ́ bi adarí kejì'Alawi dynasty.[2] Òun ni ọmọkùnrin kejeMoulay Sharif ó sì fi ìgbà kan jẹ́ Gómìnà àgbègbè Fez àti àríwá Morocco láti ọdún 1667 títí di ìgbà ikú arákùnrin rẹ̀, SultanMoulay Rashid ní ọdún 1672. Wọ́n kéde rẹ̀ gẹ́gẹ́ sultan níFez, ṣùgbọ́n òun àtiMoulay Ahmed ben Mehrez, ẹni kejì tí ó pe ara rẹ̀ ní Sultan jà fún ọ̀pọ̀ ọdún, Moulay Rashid padà fi ayé sílẹ̀ ní ọdún 1687. Moulay Ismail wà lórí oyè fún ọdún márùnléládọ́ta, èyí sì mú kí ó jẹ́ Sultan tí ó pẹ́ lórí oyè jù ní Morocco. Nígbà ayé rẹ̀, Moulay ní ìyàwó tí ó tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹta àti ọmọ tí ó tó ẹgbẹ̀rin.
- ↑"Morocco (Alaoui Dynasty)".www.usa-morocco.org. Archived fromthe original on 29 August 2005. Retrieved10 April 2018. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑Abun-Nasr, J.M.,A History of the Maghrib in the Islamic Period, page 230. Cambridge University Press, 1987