Fig jẹ́ èso tó ṣe é jẹ tiFicus carica, ọ̀kan lára àwọn ẹ̀yà igi kékeré ti àwọn igi olódòdó láti ìdílé Moraceae, tó jẹ́ ìbílẹ̀ sí àwọn ènìyàn ní Mediterranean pẹ̀lú àwọn tó wà ní apá Ìwọ̀-oòrùn àti apá Gúúsù Asia. Wọ́n ti máa ń gbìn ín láti ìgbà àtijọ́, ó sì máa ń hù káàkiri àgbáyé.[3][4]Ficus carica jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀yà genusFicus, ó sì ní ẹ̀yà ẹgbẹ̀rin (800) mìíràn.
Orúkọ yìífig, tí wọ́n ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì ní sẹ́ńtúrì kẹtàlá (13th century), jẹ yọ láti èdè Faransé ìgbaanì tó jẹ́figue.[5] Èdè Ítálì náà nífico, tó jẹ yọ látara Latinficus. Orúkọcaprifig,Ficus caprificus Risso, náà jẹ yọ láti inú èdè Latincapro (goat) àti Gẹ̀ẹ́sìfig.[6]
Ficus carica jẹ́ igi gynodioecious, èyí tó jẹ́ igi tó fẹ́, tí ò sì ga púpọ̀, tó sì máa ń ga tó ìwọ̀n méje sí mẹ́wàá (7–10m (23–33ft)) ní gíga, pẹ̀lú èpo funfun. Ewé rẹ̀ tó12–25cm (41⁄2–10in) ní gígùn, àti10–18cm (4–7in) ní fífẹ̀, ó sì máa ń láwẹ́ lóríṣiríṣi.
Èso fig máa ń hù ní wọ̀ǹba, wọ́n sì ń pè é nísyconium, ètí tó ní òdòdó tó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlà lára. Àwọn òdòdó kékeré rẹ̀ jọ kọ́ọ̀pù. Èso rẹ̀ máa ń ní kóró kan ṣoṣo, ní àárín rẹ̀.Ó ṣí sílẹ̀ ní àárín, kóró inú rẹ̀ sì tóbi. At maturity, these 'seeds' (actually single-seeded fruits) line the inside of each fig.[7]
↑1771 illustration from Trew, C.J.,Plantae selectae quarum imagines ad exemplaria naturalia Londini, in hortis curiosorum nutrit, vol. 8: t. 73 (1771), drawing by G.D. Ehret