Cleopatra VII Philopator jẹ́ ọbabìnrin Ptolemaic tí Orílẹ̀-èdèẸ́gíptì Ayéijọ́un láàrin ọdún 51 sí 30 BC.[note 3] Ó jẹ́ ọmọ ìran Ptolemaic, àti ọmọ ẹni tí ó pilẹ̀ ìran náà,Ptolemy I Soter, ẹni tó jẹ́ ológun àti ọ̀rẹ́Alexander the Great.[note 4] Lẹ́yìn ikú Cleopatra, Egypt di ọkàn lára àwọn orílẹ̀ èdè tí ó wà lábé ìjọbaÌjọba Rómù. Bí ó tilè jẹ́ wípé èdè tí Cleopatra kọ́kọ́ mọ̀ niasKoine Greek, òun nìkan ni ará Macedonia tí ó dárí Egypti tí ó sì tún kó èdè àwọn ará Egypti.[note 5]
Ní ọdún 58 BC, Cleopatra tẹ̀lé bàbá rẹ̀,Ptolemy XII Auletes, nígbà tí ó sá lọ Rómù lẹ́yìn ìgbà tí Egypti dìde si, tí eléyìí sì fún ọmọ rẹ̀,Berenice IV láti gba ìtẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Wọn pa Berenice IV ní ọdún 55 nígbà tí Ptolemy padà sí Egypti pẹ̀lú àwọn ológun Rómù. Nígbà tí Ptolemy fi ayé sílè ní ọdun in 51, àpapọ̀ ijoba Cleopatra àti arákùnrin rẹ̀,Ptolemy XIII bẹ̀rẹ̀, ṣùgbọ́n ìjà láàrin wọn fa ogun abẹ́lé. Léyìn ìgbàJuliu Késárì ségun ọ̀rẹ́ Ptolemy XIII kan,Pompey lójú ogun, ó sá lọ Egypti. Pompey jẹ́ ọ̀rẹ́ síPtolemy XII, ṣùgbọ́n Ptolemy XIII rán àwọn ológun rẹ̀ láti pa Pompey lẹyìn ìgbà tí àwọn ọmọ isẹ́ rẹ̀ láàfin gbá ní ìyànjú láti pa Pompey kí Caesar tó dé. Nítorí èyí, Caesar gbìyànjú láti parí ìjà tó wà láàrin Ptolemy àti Cleopatra, ṣùgbọ́n olórí àwọn tó ń gbá Pompey ní ìyànjú, Potheinos wòye pé ìkan tí Caesar fẹ́ ṣe ma ran Cleopatra lọ́wọ́. Nítorí náà, àwọn ọmọ ogun rẹ̀ká òun àti Caesar mọ́ ààfin. Léyìn ìgbà díè tí ogun náà bẹ̀rẹ̀, àwọn ológun mìíràn dé láti ran Caesar lọ́wọ́, Ptolemy XIII kú nígbà ogun tó ṣẹlẹ̀ Nílé.
Àṣìṣe ìtọ́kasí:<ref>
tags exist for a group named "note", but no corresponding<references group="note"/>
tag was found