Movatterモバイル変換


[0]ホーム

URL:


Jump to content
Wikipedia
Ṣe àwáàrí

Benin

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Republic of Benin
Orílẹ̀-èdè Olómìnira ilẹ̀ Bẹ̀nẹ̀

République du Bénin
Motto: "Fraternité, Justice, Travail"  (French)
"Fraternity, Justice, Labour"
Orin ìyìn: L'Aube Nouvelle  (French)
The Dawn of a New Day
Location of Benin
OlùìlúÀjàṣẹ́1
Ìlú tótóbijùlọKútọ̀nú
Àwọn èdè ìṣẹ́ọbaFaransé
Orúkọ aráàlúAra Benin; Omo ile Benin
ÌjọbaOselu egbe oloselu pupo
Patrice Talon
Òmìnira 
kúrò lọ́wọ́Fránsì
• Ọjọ́
August 1,1960
Ìtóbi
• Total
[convert: invalid number] (101st)
Alábùgbé
• July 2005 estimate
84390002 (89th)
• 2009 census
6769914
• Ìdìmọ́ra
75/km2 (194.2/sq mi) (118th3)
GDP (PPP)2008 estimate
• Total
$13.014 billion[1] (140th)
• Per capita
$1,605[1] (166th)
GDP (nominal)2008 estimate
• Total
$6.940 billion[1]
• Per capita
$856[1]
Gini (2003)36.5
medium
HDI (2007) 0.437
Error: Invalid HDI value · 163rd
OwónínáWest African CFA franc (XOF)
Ibi àkókòUTC+1 (WAT)
• Ìgbà oru (DST)
UTC+1 (not observed)
Ojúọ̀nà ọkọ́ọ̀tún
Àmì tẹlifóònù229
ISO 3166 codeBJ
Internet TLD.bj
  1. Cotonou is the seat of government.
  2. Estimates for this country explicitly take into account the effects of excess mortality due to AIDS; this can result in lower life expectancy, higher infant mortality and death rates, lower population and growth rates, and changes in the distribution of population by age and sex than would otherwise be expected.
  3. Rank based on 2005 estimate.

Bẹ̀nẹ̀,[lower-alpha 1]tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́Orílẹ̀-èdè Olómìnira Bẹ̀nẹ̀,[lower-alpha 2] ni a mọ̀ tẹ́lẹ̀ síDahomey,[3]Orílẹ̀-èdè Olómìnira ilẹ̀ Bẹ̀nẹ̀ jẹ́ orílẹ̀-èdè níÌwọ̀orùn Áfríkà. Ó ní bodè pẹ̀lúTógò ní apá ìwọòrùn,Nàìjíríà ní apá ìlaòrùn, àtiBọ̀kínà Fasò àtiNáíjà ní àríwá. Ní gúúsù ó jẹ́Etíòkun Benin (Bight of Benin), tí ó sì súnmọ́ apáGulf of Guinea ní agbègbè ìyàngbẹ ilẹ̀ tí ó sùnmọ́Atlantic Ocean.[4] Olú ìlú orílẹ̀-_èdè náà niPorto-Novo, nígbà tí ilé -ìjọba tí ń darí ìṣàkóso oríl-èdè náà wà ní ìlúCotonou tí ó jẹ́ ìlú tí èrò pọ̀ sí jùlọ ní orílẹ̀-èdè náà.[5]Orílẹ̀-èdè Bẹ̀nẹ̀ saare ilẹ̀ tí ó tó 112,622|km2,[6] àwọn olùgbé inẹ̀ sì tó 14.054.000 mílíọ́nù, tí wọn sì ń fi ohun ògbìn bíiepo àtiòwú ṣe ọrọ̀ ajé.[7][8]

(pípè/bɨˈnɪn/

láarin 17 century sí 19 century, ìṣèjọba tí ó wà ní Bẹ̀nẹ̀ ni Ilẹ̀ Ọba Dahomey, tí ó diPorto-Novo

lònìí. Ojú ọ̀nà tí wọ́n ń kóẹrú gbà làsìkò ọdún 27th century látàrí ìtanisóko-ẹrú lásìkò náà. Àwọn Faransé olówò-ẹrú àmúnisìn fi ìlú náà sábẹ́ ìkan nínú àwọn ìlú amọ́nà rẹ̀ ní ọdún 1894 tí ó sì di ''French Dahomey''. Ọdún 1960 ni Dahomey gba òmìniria kúrò lábẹ́ ìjọba Faransé olówò-ẹrú àmúnisìn. Oríṣiríṣi ìjọba ni orílẹ̀-èdè Bẹ̀nẹ̀ ti ní tí ó fi mọ́ ìjọba ológun àti ìdìtẹ̀gbajọba wọn pẹ̀lú. Àwọn ẹgbẹ́ ìṣèlú tí ó wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀ ni People's Republic of Benin láàrín ọdún 1975 sí ọdún 1990. Ọdún 1991 ni wọ́n dá àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú púpọ̀ sílẹ̀ ní orílẹ̀-èdè náà.

Orúkọ rẹ̀

[àtúnṣe |àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Dahomey ni wọ́n ń pe orilẹ̀-èdè yìí ṣáájú àti lẹ́yìn ìgbòmìnira wọn kúrò lọ́wọ́ orílẹ̀-èdè Faransé ní ọjọ́ kínní oṣù kẹjọ ọdún 1960. Ọgbọ̀-ọjọ́ oṣù kọkànlá ọdún 1975 ni àwọn ológun dìtẹ̀ gba ìjọba ni wọ́n yí orúkọ orílẹ̀-èdè náà padà sí ''Benin''. Orúkọ yí ni wọ́n mú lati ara àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sọ èdè Fon tí wọ́n wá láti ilẹ̀ Ìbíní ní orílẹ̀-èdèNàìjíríà.

[9]

Ìtàn ìdásilẹ̀ orílẹ̀-èdè náà

[àtúnṣe |àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Map of theKingdom of Dahomey, 1793

Ṣaájú ọdún 1600 ni onírúurú ẹ̀yà àti àwọn elédè ti wà ní ilẹ̀ Ọba Dahomey tí kálukú wọn sì ń ṣèlú wọn láàyè ara wọn. Lára àwọn ẹ̀yà tí wọ́n wà ní Dahomey ni ẹ̀yàẸ̀yà Aja,ẹ̀yà Gbe, ẹ̀yàYorùbá, nígbà tí àwọn ẹ̀yà. mìíràn tí wọ́n ń gbé ni ọwọ́ inú jẹ́ẹ̀yà Ìbarìbá tí a ti rí àwọn ẹ̀ya èdè mìíràn bíi ''Mahi'', ''Gedevi'' àti àwọn ènìyàn ''Kabye''. Ilẹ̀ ỌbaỌ̀yọ́

Ilú-ọba Ọ̀yọ́ ni ó wà tí kò jìnà sí apá ìlà-oòrùn sí ilẹ̀ Dahomey ni ipa àwọn ọmọ ogunỌ̀yọ́ le koko lórí àwọn olùgbé ilẹ̀ Dahomey tí wọn sì ń gbaOwó orí lọ́wọ́ wọn. Èyí di ohun ìtàn ní ọdún 17 sí 18 century nígbà tí àwọnènìyàn Fon dá ilẹ̀ Ọba Abomey sílẹ̀.

Awon ipinle ijoba

[àtúnṣe |àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Àwọn ìpínlẹ̀ ìjọba Benin

Ile Benin je pinpin siapá mejila (French: départements), awon wonyi si tun je pinpin siibile 77. Ni odun 1999 ni won pin awon apa ijoba abele mefa to wa tele si mejila.

  1. Alibori
  2. Atakora
  3. Atlantique
  4. Borgou
  5. Collines
  6. Donga
  7. Kouffo
  8. Littoral
  9. Mono
  10. Ouémé
  11. Plateau
  12. Zou

Jọ́gíráfì

[àtúnṣe |àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Benin jẹ́ ile san lati Ariwa de Guusu ni ilaoorun Afrika, o dubule larinAgbedeméjì ayé (Equator) atiÌlà-ooru Alákàn (Tropic of Cancer). Ìlàìdùbúlẹ̀ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti 6°30′A dé 12°30′A, bẹ́ ẹ̀ sì ni ìlàìnàró rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti 1°L dé 3°40′L.

Pelu agbegbe ile to to112622 km2 Benin fe latiOdò Niger ni ariwa titi de Okun Atlantiki ni guusu, ijinnasi to je650 km(400 mi). Botilejepe ni iwon ile eba odo re je121 km(75 mi) iwon ile orile-ede na ni ibi totifeju je325 km(200 mi).

Ikan ninu awon orile-ede tokerejulo ni Iwoorun Afrika ni Benin. O kere ni ilopo mejo si Naijiria to ni bode mo si ilaoorun. Sugbon o tobi ni ilopo meji si Togo to ni bode mo si iwoorun. Maapu ile Benin fihan pe awon oke re ko fi be yato si ara won (idasarin awon oke re je200 m).[10]

A le pin oril-ede na si apa merin lati gusu de ariwa. Ibi ẹ̀kun omi irele, oniyanrin (igbeleke togajulo10 m) je, lopojulo,10 km ni fife. O je ile erofo to ni awo adagun odo ati osa ti won japo mookun. Awon ilegiga apagusu Benin (igasoke larin20 m ati200 m) pinya si ra won nitori awon afonifoji to la koja lati ariwa de gusu legbe awon odoCouffo,Zou, andOueme.

Isuna

[àtúnṣe |àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Isuna ile Benin je ti alaidagbasoke, o si gbojule ise agbe aroje, ogbin owu ati okowo agbegbe. Owu tita lo je 40% GDP ati bi 80% ipawo oja okere iseoba.[11] Idagbasoke eso-ise dasarin 5% ni bi odun meje seyin, sugbon iposi iyearabudo ko je ki iposi yi o ni ipa kankan. Igbowolori (owon) ti din sile ni bi odun melo se yin.CFA franc ni owonina ile Benin.


Dimográfì

[àtúnṣe |àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Maapu Bénin

Ogunlogo iyearabudo ile Benin n gbe ni gusu. Won je ọ̀dọ́, peluàsìkò ìgbẹ̀mí to je odun 59. Awon eya ede Afrika bi 49 lo wa ni Benin; awon wonyi tedo kakiri. Awon eya ede yi ni Yoruba ni gusuilaoorun (ti won wa lati Naijiria ni odunrun 12la); Dendi ni agbegbe ariwa-arin (won kowa lati Mali ni orundun 16un); Bariba ati Fulbe ni ariwailaoorun; Betammaribe ati Somba ni Atacora Range; Fon ni ayika agbegbe Abomey ni Arin Gusu; ati Mina, Xueda, ati Aja (ti won wa lati Togo) ni ekun odo.[10]

Fon ni eya ede topojulo pelu 1.4 legbegberun iyearabudo to n soede Fon, Yoruba tele won pelu 1.2 legbegberun, Aja (600,000), Bariba (460,000), Ayizo (330,000), the Fulbe (tabi Fulani, Peul ati Fula) (310,000), ati awon Gun (240,000). Bakanna ni leba awon ebute ni gusu a le ri awon omo-omo awon eru ti won kopada wa latiBrasil. Bakanna die tun wa lati ileEurope, agaga awon araFransi ati awon eniyan lati apaariwa Asia biLebanon ati Ilaoorun Asia biIndia.

Esin

[àtúnṣe |àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Gege bi onka 2002 se fihan, 42.8% je Elesin Kristi (27.1% je Katholiki, Selestial 5%, Methodisti 3.2%, other Protestanti 2.2%, awon miran 5.3%), 24.4% je Musulumi, 17% je Elesin ibile, 15.5% awon miran.[12]

Èdè

[àtúnṣe |àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ede iseoba jeFaransé sugbon sibesibe awon ede abinibi bi Fon atiYoruba na tu gbajumo agaga ni apa gusu. ni apa ariwa awon ede bi bariba ati fula gbajumo.

Awon eya eniyan

[àtúnṣe |àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

99% je àwon omo Afrika (Yoruba, Fon, Aja, Bariba at.bb.lo), awon omoEurope ko ju 10,000 lo.

Ilera ati itoju

[àtúnṣe |àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ni arin ewaodun '80, awon omo ile Benin ti won le gba itoju ilera to yeke din ni 30% iyearabudo, nitori eyi Benin ni ofo omode togajulo ni Afrika. Leyin Idawose Bamako iyato to dara sele, eyi si je ki ipese ilera o wa fun opo awon iyearabudo.[13][14]

Ikeko

[àtúnṣe |àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ikeko ko pondandan be si ni ki se ofe.[15] Bakanna awon odomokunrin poju awon odomobirin lo ni ile eko. Ipin awon akeko si awon oluko posoke lati 36:1 ni 1990 de 53:1 ni 1997. Aimookomooka je 60% awon iyearabudo.[16].

Sistemu Eko

[àtúnṣe |àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Awon akoko ti ile-eko kookan n gba[17]

  • Ile-eko Alakobere: odun 6
  • Ile-eko Keji kekere: odun 4
  • Ile-eko Keji agba: odun 3
  • Iwe-eri Barchelor: odun 3
  • Iwe-eri Master: odun 4


Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí.

Ẹ lefẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ látifẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ.


Awon Itokasi

[àtúnṣe |àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. 1.01.11.21.3"Benin". International Monetary Fund. Retrieved2009-04-22. 
  2. Àdàkọ:Cite EPD
  3. "Dahomey Announces Its Name Will Be Benin" (in en-US). The New York Times. 1 December 1975. ISSN 0362-4331. https://www.nytimes.com/1975/12/01/archives/dahomey-announces-its-name-will-be-benin.html. 
  4. Hughes, R. H.; Hughes, J. S. (1992). A Directory of African Wetlands. IUCN. p. 301. ISBN 978-2-88032-949-5. https://books.google.com/books?id=VLjafeXa3gMC. Retrieved 12 October 2015. 
  5. Àdàkọ:Multiref2
  6. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid<ref> tag; no text was provided for refs namedReferenceA
  7. "FAO Initiative on Soaring Food Prices".Food and Agriculture Organization of the United Nations. Archived fromthe original on 2012-10-24. Retrieved29 June 2010. 
  8. "Major Industries in Benin".Arise IIP. Retrieved2024-06-23. 
  9. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid<ref> tag; no text was provided for refs namednyt19752
  10. 10.010.1"Background Note: Benin". U.S. Department of State (June 2008).Àyọkà yìí mú ìkọ̀wé láti orísun yìí tí ó wà ni ìgboro.
  11. Background Note: Benin
  12. International Religious Freedom Report 2007: Benin. United States Bureau of Democracy, Human Rights and Labor (14 Osu kesan, 2007).
  13. "Bamako Initiative revitalizes primary health care in Benin". Retrieved 28-12-2006. Check date values in:|access-date= (help)
  14. "Implementation of the Bamako Initiative: strategies in Benin and Guinea". Retrieved 28-12-2006. Check date values in:|access-date= (help)
  15. "Benin".Findings on the Worst Forms of Child Labor (2001). Bureau of International Labor Affairs, Ile-ise Alakoso Ikeko ile Amerika (2002).
  16. Education: ProgramsArchived 2008-06-13 at theWayback Machine.. USAID Benin
  17. Eto Eko ni Orile-ede BeninArchived 2008-07-27 at theWayback Machine.. Ile-ise Alasoju ile Amerika, Κutonu
Àwọn ìjápọ̀ sí àwọn àyọkà bíbíramu
Àwọnorílẹ̀-èdè apàṣẹ
Algeria ·Angola ·Benin ·Botswana ·Burkina Faso ·Burundi ·Cameroon ·Cape Verde ·Central African Republic ·Chad ·Comoros ·Democratic Republic of the Congo ·Republic of the Congo ·Côte d'Ivoire (Ivory Coast) ·Djibouti ·Egypt ·Equatorial Guinea ·Eritrea ·Ethiopia · France(Mayotte ·Réunion) ·Gabon ·The Gambia ·Ghana ·Guinea ·Guinea-Bissau · Italy(Pantelleria) ·Kenya ·Lesotho ·Liberia ·Libya ·Madagascar ·Màláwì ·Mali ·Mauritania ·Mauritius ·Morocco ·Mozambique ·Namibia ·Niger ·Nigeria · Portugal(Madeira) ·Rùwándà ·São Tomé and Príncipe ·Senegal ·Seychelles ·Sierra Leone ·Somalia ·South Africa ·South Sudan(from 9 July 2011) · Spain(Canary Islands ·Ceuta ·Melilla ·Plazas de soberanía) ·Sudan ·Swaziland ·Togo ·Tanzania ·Tunisia ·Uganda · Yemen(Socotra) ·Zambia ·Zimbabwe
States with
limited recognition
Dependencies
Unclear sovereignty
Àyọkà dáradára


Àṣìṣe ìtọ́kasí:<ref> tags exist for a group named "lower-alpha", but no corresponding<references group="lower-alpha"/> tag was found

Jẹ́ kíkójáde láti "https://yo.wikipedia.org/w/index.php?title=Benin&oldid=609687"
Àwọn ẹ̀ka:
Áwọn ẹ̀ka bíbòmọ́lẹ̀:

[8]ページ先頭

©2009-2025 Movatter.jp