Barack Hussein Obama Jr. (ojó-ìbí rẹ̀ ni ọjọ́ kẹrin oṣù kẹjọ ọdún 1961) jẹ́olóṣèlú àti Ààrẹ Orílẹ̀-èdè ilẹ̀Amerika tele.[1] Ó jẹ́ òloṣèlú orílẹ̀ èdè Améríkà, ọmọ ilé ìgbìmó aṣòfin látiìpínlè Illinois, ọmọ ẹgbéòṣèlú Democrat. Barack Obama jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn òṣèlú méjì tí wón figagbága láti jẹ Ààrẹ ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Ẹni èkejì niJohn Mccain. Ni ọjọ́ kẹrin oṣù kọkànlá ọdún 2008 Obama wọlé ìbò fún ipò Ààrẹ ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Obama gorí oyè níogún jó osù kinni odún2009. Barack Obama jéaláwọ̀ dúdú àkọ́kọ́ tí òkan nínú àwọn egbé òṣèlú nlá ti ilè Amẹ́ríkà fún ní ànfàní láti kópa nínú eré ìje àti diÀàrẹ ilè Amerika láti ẹgbẹ́ òṣèlúDemocrat.
Wón bí Barack Obama ní ìlúHonolulu,ìpínlè Hawaii ní ọdun 1961. Àwòn òbí ré rí ara won ní ìgbà tí wón nka ìwé ní ilé èkó Unifásítì Hawaii ní ìlu Manoa. Bàba rè wá láti orílè èdèKenya.[2][3]Barack Hussein Obama- àgbà, lọ ka ìwé nípa òrò ajé ní ilè Amerika. Ìya rè, ènìyàn funfun, ọmọ ilè Améríkà,Stanley Ann Dunham, jé ọmọ ilé èkó Unifásítì láti ìlu Wichitta,ìpínlè Kansas. Àwọn òbí ìya rè lòdì sí àjọṣe àwọn méjèjì, ṣùgbón wón fé ara wọn ní odún1960.[4]Ọdún méjì léhìn tí wón bí Obama, bàbá rè lọ si Howard fún ìtèsíwájú èkọ rè, ṣùgbón kò mú ẹbí rè lọ nítorí àìsí owó. Ní àìpé ọjó wón yapa. Ní ìgbà èkó rè ní Howard, Obama- àgbà fé Ruth Nidesand, ẹni tí ó bá padà sí orílè èdè Kenya léhìn ìparí èkò rè. Ruth Nidesand jé ìyàwó rè ẹ̀kẹ́ta, wón sì ní ọmọ méjì. Ní orílè èdè Kenya, Obama- àgbà bèrè iṣé ní ilé iṣé tí ó nwa epo ròbì, léhìn èyí, ó ṣiṣé fún ìjọba, gégébí olóòtú ètò ọrò ajé. Ó fi ojú kan ọmọ rè, Obama, ní ìgbàkan péré- ní ìgbà tí oní tòhún pé ọmọ ọdún méwàá. Obama- àgbà fi arapa nínú àgbákò ọkò nípa èyí tí ó sọ ẹsè méjèjì nù. Ní ìgbà tí ó pé ọmọ ọdún mérin-dí-láàdóta, ní ọdún 1982, ó sọ èmí rè nù nínú àgbákò ọkò.
Léhìn ìyapa pèlu bàba Obama, ìya rè fé Lolo Soetoro, ọmọ ilé èkó gíga unifasiti láti orílè èdèIndonesia. Ní ọdún1967 ó sì bá Lolo Soetoro lọ sí Indonesia. Barack Obama ní ọbàkàn, obìnrin, ọmọ Lolo àti Stanley Ann. Stanley Ann Dunham pèhìndà ní ọdún1995.
↑Rudin, Ken (December 23, 2009)."Today's Junkie segment on TOTN: a political review Of 2009".Talk of the Nation (Political Junkie blog). NPR. RetrievedApril 18, 2010.We began with the historic inauguration on January 20 – yes, the first president ever born in Hawaii