| Bùkọ́lá Àwoyẹmí | |
|---|---|
| Ọjọ́ìbí | 1988 Kwara |
| Orúkọ míràn | Arugbá |
| Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
| Iṣẹ́ | òṣèrébìnrin |
| Olólùfẹ́ | Dàmọ́lá Ọlátúnjí |
Bùkọ́lá Àwoyẹmí tí gbogbo ènìyàn mọ̀ síArugbá, tí wọ́n bí lọ́dún 1988 jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin ọmọ bíbíìpínlẹ̀ Kwara lórílẹ̀-èdèNàìjíríà.[1] Òun ni ìyàwó gbajúmọ̀ òṣèré mìíràn tí ó ń jẹ́Dàmọ́lá Ọlátúnjí.[1]Ó gba orúkọ ìnagijẹ rẹ̀, Arugbá látàrí ipa tí ó kó nínú sinimá àgbéléwò kan tí ògbóǹtarìgì òní-sinimá, Túndé Kèlání gbé jáde lọ́dún 2008.[2]
Wọ́n bí Bùkọ́lá Arugbá ní ìpínlẹ̀ Kwara lọ́dún 1988. Láti ìgbà èwe ni Bùkọ́lá tí fẹ́ràn láti di eléré tíátà. Ó kàwé gbàwé ẹ̀rí nínú ìmọ̀ iṣẹ́ Tíátà ní ifáfitì ìjọba àpapọ̀ ní Ìlọrin, University of Ilorin. Nígbà tí ó ń kẹ́kọ̀ọ́ ló ti ń gbìyànjú láti máa ṣeré tíátà, ṣùgbọ́n ìràwọ̀ rẹ̀ kò tàn àfi ìgbà tí ó kópa nínú sinimá àgbéléwò tí Túndé Kèlání dárí lọ́dún 2008,tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Arugbá. Lẹ́yìn náà o tún kópa nínú "Poisonous Affair" àti àwọn sinimá-àgbéléwò gbankọgbì mìíràn lédèYorùbá. "Ìgbà Ǹ Bá Jó" ni sinimá àgbéléwò àkọ́kọ́ tí Bùkọ́lá Àwoyẹmí ṣe agbátẹrù rẹ̀ fún ara rẹ̀ lọ́dún 2013.