Acarajé inSalvador, Brazil | |
| Alternative names | Acara, Àkàrà, Kosai |
|---|---|
| Course | Street-food |
| Place of origin | West Africa |
| Region or state | West Africa andSouth America |
| Associatednational cuisine | Nigeria,Ghana,Togo,Benin,Mali,Gambia andBrazil |
| Serving temperature | Hot |
| Main ingredients | Black eyed peas, deep-fried indendê (palm oil) |
Àdàkọ:Wikibooks-inline
| |
Àkàrà jẹ́ oúnjẹ abínibí ìbílẹ̀ ilẹ̀Yorùbá àti púpọ̀ nínú ilẹ̀Adúláwọ̀.
Àkàrà wà nínú àrà tí wọ́n ma ń fiẹ̀wà dá. Wọ́n ma ń rẹ ẹ̀wà sínú omi, fún bii ọgbọ̀n ìṣẹ́jú tàbí wákàtí kan kí ó lè rọ̀. Lẹ́yìn èyí, wọn yóò fiata,àlùbọ́sà,edé àti àwọn nkan mìíràn tí ó bá wù wá si kí wọ́n tó lọ̀ọ́ kúná. Lẹ́yìn tí wọ́n bá lọ̀ọ́ tán, wọn yóò gbéepo tàbíòróró kaná tí wọn yóò sì ma dá ẹ̀wà náà sínú epo yí kí ó lè dín.[1][2]
Wọ́n lè jẹ àkàrà lásán, wọ́n lè fi jẹ̀kọ, jẹ búrẹ́dì, mùkọ, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.[3]
Akara ní àwọn èròjà láti múni sanra, torí àwọn èròjà proteins, vitamins àti minerals bí i calcium, iron àti zinc inú rẹ̀.[4][5] Àmọ́ ṣáá, àwọn èròjà inú rẹ̀ lè ti dínkù nítorí àwọn àfikún kan bí iphytates, fibers, lectins, polyphenols àti tannins tí kì í ṣe ara lóore.[4]